Àwo Oúnjẹ Ìlera (Yoruba)

Yoruba_Aug2015

Àwo àte oúnjẹ aṣaralóore la ṣẹ àgbékalè rè láti ọwọ́ àwọ́n onímò ti ilé-ìwé ètò ìlera ọ̀fẹ́ ní Havard tí a sì ṣẹ àgbéjadè rẹ̀ ní ilé-iṣẹ́ àgbéjadè ètò ìlera, èyí tó jẹ́ fún láti pe àkíyèsí wa sì oúnjẹ tó pé – yálà a bùú sínú abó tàbí sínú ike tí a fi ń gbé oúnjẹ pamọ́. Fi àpẹẹrẹ rẹ̀ kan sára fíríìjì láti máa dúró gẹ́gẹ́ bíi ape-àkíyèsí sí ìlera, àti jíjẹ́ oúnjẹ tó pé tó sì sara-lóore.

  • Mú kí oúnjẹ re kún fún ewébẹ̀ àti èèso – Ìdajì abọ́:

Lọ fún àwò lórísìírísìí, sì rántí pé ọ̀dùnkún kìí ṣẹ ewébè tí a lè kà kún gbíbe ní ìlera nítorí wọ́n ní ipa tí kò dára lórí ìtọ̀-súgà.

  • Lọ fún oúnjẹ wóóró irúgbìn kan – ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ìdá mẹ́rin àbọ̀:

Oúnjẹ oníhóró ẹlẹ́yọ̀ – wíìtì, báálì, èèso wíìtì, qúínóà, ògì, ọkà, ìresì àti oúnjẹ tí a sè pèlú wọn, bíi oúnjẹ tí a fi àgbàdo àti ìrẹsì ṣẹ – wọ́n ní àbáyọrí díè lóri ìtò- súgà àti inslulínì ju búrédì funfun lọ, ìresì funfun àti a àwọ́n oúnjẹ irúgbìn wóró kan yókù tí a tún ṣe.

  • Oúnjẹ Amúnidàgbà – ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ìdá mẹ́rin àbọ̀:

Ẹja, adìye, ẹ̀wà àti èèso ẹlẹ́pà bíi ẹ̀pà sísè, yíyan, kaṣú abbl ló dára, àwọn oúnjẹ ámaradàgbà míì tí a mú láti oríson mìíran tí – a lè dàpọ̀ mọ́ sàláàdì, àti tí a tún lè jẹ pèlú ewébè nínú abọ́. Jẹ ẹran níwọ̀nba, kí o sì sá fún ẹran bíi sọ́sáàjì àti bákóònù.

  • Oúnjẹ ọlọ́ràá:

Lo òróró ìsebè tó kún fún ìlera tó wà fún ìdágbásókè ara láti mú kí ara wa wà lálàáfíà bíi òróró ólívì, sóyà, àgbàdo abbl. Kí o sì sá fún àwọn òróró tí ó ń mú ní sanra tó ní àwọn ohun tí kò lè ṣara lóore. Rántí pé ọ̀rá ìwọ̀nba kò túnmọ̀ sí pé o wà ní “Ìlera Pípé”.

  • Mu omi, tíì tàbí kofí:

Sá fún àwọn ohun mímu tó dùn, dín mílíìkì òòjọ́ mímu kù sí èèkan tàbí èèmejì lójúmọ́, kí osì mu ife kékére kan lójoojúmọ́.

  • Máa wà lákínkanjú ní gbogbo ìgbà:

Àwọn àwòrán ohun pupa/ẹlẹ́jẹ̀ tó ń sáré kiri nínú àwòran àwo ìléra jẹ́ ìrántí láti máa wà ní akínkanjú àti ọ̀nà láti dín ọ̀sùwòn ìwọ̀n kù.

Kókó inú àpèjúwe oúnjẹ aṣaralóore ní láti dúró lé ìwọ̀n oúnjẹ tó pé:

  • Irúfé oúnjẹ afáralókun tó wà nínú oúnjẹ se pàtàkì ju oye oúnjẹ afáralókun tó wà nínú oúnjẹ lọ, torí àwọn oríson oúnjẹ afáralókun bíi ewébè (àti òdùnkún), èèso, oúnjẹ wóró irúgbìn kan, àti ẹ̀wà jẹ́ èyí tó ní ìlera ju àwọn yókù lọ.
  • Ó tún gba ni níyànjú pé oníbárà gbọ́dọ̀ yàgò fún àwọn ohun mímu onísúgà, èyí tó jẹ́ orísun tó tóbi jù fún ìsanra – Ó wà lórí díẹ̀ lára àwọn oúnjẹ tó ní ìdíyelé.
  • Oúnjẹ ìlera yìí náà tún gba oníbárà níyànjú láti lo òróró tó ní ìlera nínú; kò sì ní èyí tí ó pòjù lọ nínú ìwọ̀n ìtóbi tí ènìyàn gbọ́dọ̀ ní lójúmọ́ láti ara oríson ọ̀rá tó mú ìlera dání.

Translation assistance provided by Dr. Sally N. Adebamowo

Terms of Use

The contents of this website are for educational purposes and are not intended to offer personal medical advice. You should seek the advice of your physician or other qualified health provider with any questions you may have regarding a medical condition. Never disregard professional medical advice or delay in seeking it because of something you have read on this website. The Nutrition Source does not recommend or endorse any products.